2 Kings 14:17-20

17 aAmasiah ọmọ Joaṣi ọba Juda gbé fún ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún lẹ́yìn ikú Jehoaṣi ọmọ Jehoahasi ọba Israẹli. 18Fún ti ìyókù iṣẹ́ rẹ̀ nígbà ìjọba Amasiah, ṣé a kò kọ wọ́n sínú ìwé ìtàn ayé àwọn ọba Juda?

19Wọ́n dìtẹ̀ sí i ní Jerusalẹmu, ó sì sálọ sí Lakiṣi, ṣùgbọ́n wọ́n rán àwọn ọkùnrin tẹ̀lé e sí Lakiṣi, wọ́n sì pa á síbẹ̀. 20Wọ́n gbé e padà pẹ̀lú ẹṣin, a sì sin ín sí Jerusalẹmu pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀, ní ìlú ńlá ti Dafidi.

Copyright information for YorBMYO